O. Daf 135:5-12
O. Daf 135:5-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ. Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo. O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá. Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko. Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba. Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani: O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀.
O. Daf 135:5-12 Yoruba Bible (YCE)
Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi, ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ. Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣe lọ́run ati láyé, ninu òkun ati ninu ibú. Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé, ó fi mànàmáná fún òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀. Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti, ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run; ó pa àwọn ọba alágbára: Sihoni ọba àwọn Amori, Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀; ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.
O. Daf 135:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí tí èmi mọ̀ pé OLúWA tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ. OLúWA ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo. Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò: ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá. Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti, àti ti ènìyàn àti ti ẹranko. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti, sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo. Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba. Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani: Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.