O. Daf 132:1-12
O. Daf 132:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, ranti Dafidi ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: Ẹniti o ti bura fun Oluwa, ti o si ṣe ileri ifẹ fun Alagbara Jakobu pe. Nitõtọ, emi kì yio wọ̀ inu agọ ile mi lọ, bẹ̃li emi kì yio gùn ori akete mi; Emi kì yio fi orun fun oju mi, tabi õgbe fun ipenpeju mi, Titi emi o fi ri ibi fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu. Kiyesi i, awa gburo rẹ̀ ni Efrata: awa ri i ninu oko ẹgàn na. Awa o lọ sinu agọ rẹ̀: awa o ma sìn nibi apoti-itisẹ rẹ̀. Oluwa, dide si ibi isimi rẹ; iwọ, ati apoti agbara rẹ. Ki a fi ododo wọ̀ awọn alufa rẹ: ki awọn enia mimọ rẹ ki o ma hó fun ayọ̀. Nitori ti Dafidi iranṣẹ rẹ, máṣe yi oju ẹni-ororo rẹ pada. Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ. Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ́ ati ẹri mi ti emi o kọ́ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ́ rẹ lailai.
O. Daf 132:1-12 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà. Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA, tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu, tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi; n kò ní sùn, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé, títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA, àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.” A gbúròó rẹ̀ ní Efurata, a rí i ní oko Jearimu. “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀; ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.” Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ, tìwọ ti àpótí agbára rẹ. Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo, kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀. Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ, má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ. OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi, èyí tí kò ní yipada; ó ní, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn, àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”
O. Daf 132:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Ẹni tí ó ti búra fún OLúWA, tí ó sì ṣe ìlérí fún Alágbára Jakọbu pé. Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi: Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi, Títí èmi ó fi rí ibi fún OLúWA, ibùjókòó fún Alágbára Jakọbu. Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata: àwa rí i nínú oko ẹgàn náà. Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ OLúWA, dìde sí ibi ìsinmi rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára rẹ. Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀. Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ Má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà. OLúWA ti búra nítòótọ́ fún Dafidi: Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.