O. Daf 13:1-6
O. Daf 13:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ o ti gbagbe mi pẹ to, Oluwa, lailai? iwọ o ti pa oju rẹ mọ́ pẹ to kuro lara mi? Emi o ti ma gbìmọ li ọkàn mi pẹ to? ti emi o ma ni ibinujẹ li ọkàn mi lojojumọ? ọta mi yio ti gberaga sori mi pẹ to? Rò o, ki o si gbohùn mi, Oluwa Ọlọrun mi: mu oju mi mọlẹ, ki emi ki o má ba sùn orun ikú. Ki ọta mi ki o má ba wipe, emi ti ṣẹgun rẹ̀; awọn ti nyọ mi lẹnu a si ma yọ̀, nigbati a ba ṣi mi nipò. Ṣugbọn emi o gbẹkẹle ãnu rẹ; ọkàn mi yio yọ̀ ni igbala rẹ. Emi o ma kọrin si Oluwa, nitoriti o ṣe fun mi li ọ̀pọlọpọ.
O. Daf 13:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé o óo wá gbàgbé mi laelae ni? Títí di ìgbà wo ni o óo fi ojú pamọ́ fún mi? Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́ tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà? Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí? Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi. Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú. Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.” Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú. Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí. N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA, nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ.
O. Daf 13:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yóò ti pẹ́ tó, OLúWA? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé? Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà, àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi? Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi? Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, OLúWA Ọlọ́run mi. Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú; Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,” àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú. Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà; ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ. Èmi ó máa kọrin sí OLúWA, nítorí ó dára sí mi.