O. Daf 128:1-4
O. Daf 128:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
IBUKÚN ni fun gbogbo ẹniti o bẹ̀ru Oluwa; ti o si nrìn li ọ̀na rẹ̀. Nitori ti iwọ o jẹ iṣẹ́ ọwọ rẹ: ibukún ni fun ọ: yio si dara fun ọ. Obinrin rẹ yio dabi àjara rere eleso pupọ li arin ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yio dabi igi olifi yi tabili rẹ ka. Kiyesi i, pe bẹ̃li a o busi i fun ọkunrin na, ti o bẹ̀ru Oluwa.
O. Daf 128:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA, tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ. Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ; bí ọmọ tií yí igi olifi ká, ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká. Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
O. Daf 128:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù OLúWA: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká. Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà, tí ó bẹ̀rù OLúWA.