O. Daf 127:1-3
O. Daf 127:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan. Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun. Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀.
O. Daf 127:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé, asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ. Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú, asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de. Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu, kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn. Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ; nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn. Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ; òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.
O. Daf 127:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí kò ṣe pé OLúWA bá kọ́ ilé náà àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni; bí kò ṣe pé OLúWA bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán. Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá; bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run. Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní OLúWA: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.