O. Daf 127:1-2
O. Daf 127:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan. Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun.
O. Daf 127:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé, asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ. Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú, asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de. Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu, kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn. Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ; nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.