O. Daf 126:1-6
O. Daf 126:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá. Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn. Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀. Oluwa mu ikólọ wa pada, bi iṣan-omi ni gusu. Awọn ti nfi omije fún irugbin yio fi ayọ ka. Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ̀ pada wá, yio si rù iti rẹ̀.
O. Daf 126:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada, ó dàbí àlá lójú wa. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀, nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé, “OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!” Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Dá ire wa pada, OLUWA, bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu. Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú, jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀. Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún, yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀.
O. Daf 126:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí OLúWA mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá. Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, OLúWA ṣe ohun ńlá fún wọn. OLúWA ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀. OLúWA mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù. Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka. Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.