O. Daf 125:1-5
O. Daf 125:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ti o gbẹkẹle Oluwa yio dabi òke Sioni, ti a kò le ṣi ni idi, bikoṣepe o duro lailai. Bi òke nla ti yi Jerusalemu ka, bẹ̃li Oluwa yi awọn enia rẹ̀ ka lati isisiyi lọ ati titi lailai. Nitori ti ọpá awọn enia buburu kì yio bà le ipin awọn olododo: ki awọn olododo ki o má ba fi ọwọ wọn le ẹ̀ṣẹ. Oluwa ṣe rere fun awọn ẹni-rere, ati fun awọn ti aiya wọn duro ṣinṣin. Bi o ṣe ti iru awọn ti nwọn yà si ipa ọ̀na wiwọ wọn: Oluwa yio jẹ ki wọn lọ pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn alafia yio wà lori Israeli.
O. Daf 125:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni, tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae. Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká, láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae. Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹ lórí ilẹ̀ àwọn olódodo, kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi. OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere, ati fún àwọn olódodo. Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹ àwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.
O. Daf 125:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA yóò dàbí òkè Sioni, tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA yí ènìyàn ká láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo; kí àwọn olódodo kí ó máa ba à fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀. OLúWA ṣe rere fún àwọn ẹni rere, àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin. Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; OLúWA yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.