O. Daf 122:1-9 - Compare All Versions

O. Daf 122:1-9 YBCV (Bibeli Mimọ)

INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa. Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu. Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan. Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa. Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi. Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere. Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ. Nitori awọn arakunrin ati awọn ẹgbẹ mi, emi o wi nisisiyi pe, Ki alafia ki o wà ninu rẹ! Nitori ile Oluwa Ọlọrun wa, emi o ma wá ire rẹ.

O. Daf 122:1-9 YCE (Yoruba Bible)

Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.” A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu. Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́, tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan. Níbi tí àwọn ẹ̀yà, àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ, láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli. Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí, àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi. Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu! “Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ! Kí alaafia ó wà ninu rẹ, kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.” Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.” Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa, èmi óo máa wá ire rẹ.

O. Daf 122:1-9 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé OLúWA.” Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ, ìwọ Jerusalẹmu. Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan. Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà OLúWA, ẹ̀rí fún Israẹli, láti máa dúpẹ́ fún orúkọ OLúWA. Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀, àti ìre nínú ààfin rẹ̀. Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi èmi yóò wí nísinsin yìí pé, kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀. Nítorí ilé OLúWA Ọlọ́run wa, èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.