O. Daf 116:1-9
O. Daf 116:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi. Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi. Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu. Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi. Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa. Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ. Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ. Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu. Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye.
O. Daf 116:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Mo fẹ́ràn OLUWA nítorí pé ó gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ mi. Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi, nítorí náà, n óo máa ké pè é níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. Tàkúté ikú yí mi ká; ìrora isà òkú dé bá mi; ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA, mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!” Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA, aláàánú ni Ọlọrun wa. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́; nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá, nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ. Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú, o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé, o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú. Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.
O. Daf 116:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi fẹ́ràn OLúWA, nítorí ó gbọ́ ohùn mi; ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú. Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè. Okùn ikú yí mi ká, ìrora isà òkú wá sórí mi; ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi. Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ OLúWA: “OLúWA, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!” OLúWA ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú. OLúWA pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí OLúWA ṣe dáradára sí ọ. Nítorí ìwọ, OLúWA, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú, Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú OLúWA ní ilẹ̀ alààyè.