O. Daf 112:7-10
O. Daf 112:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kì yio bẹ̀ru ihin buburu: aiya rẹ̀ ti mu ọ̀na kan, o gbẹkẹle Oluwa. Aiya rẹ̀ ti mulẹ, kì yio bẹ̀ru, titi yio fi ri ifẹ rẹ̀ lori awọn ọta rẹ̀. O ti fún ka, o ti fi fun awọn olupọnju; ododo rẹ̀ duro lailai; ọlá li a o fi gbé iwo rẹ̀ ga. Awọn enia buburu yio ri i, inu wọn o si bajẹ; yio pa ehin rẹ̀ keke, yio si yọ́ danu: ifẹ awọn enia buburu yio ṣegbe.
O. Daf 112:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù, ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á, níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka, òdodo rẹ̀ wà títí lae, yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá. Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i. Yóo pa eyín keke, yóo pòórá, ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán.
O. Daf 112:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú: ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OLúWA. Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á, títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú; Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé; ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá. Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́, yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù: èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.