O. Daf 11:1-7
O. Daf 11:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin? Sa kiyesi i, awọn enia buburu ti fà ọrun wọn le, nwọn ti fi ọfa sùn li oju ọṣán, ki nwọn ki o le ta a li òkunkun si ọlọkàn diduro. Bi ipilẹ ba bajẹ, kili olododo yio ṣe? Oluwa mbẹ ninu tempili mimọ́ rẹ̀, itẹ́ Oluwa mbẹ li ọrun: oju rẹ̀ nwò, ipenpeju rẹ̀ ndán awọn ọmọ enia wò. Oluwa ndán olododo wò: ṣugbọn enia buburu ati ẹniti nfẹ ìwa-agbara, ọkàn rẹ̀ korira. Lori enia buburu ni yio rọjo, ẹyín gbigbona ati imi-ọjọ ati iji gbigbona: eyi ni ipin ago wọn. Nitori olododo li Oluwa, o fẹ ododo; awọn ẹniti o duro-ṣinṣin yio ri oju rẹ̀.
O. Daf 11:1-7 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ni mo sá di; ẹ ṣe lè wí fún mi pé, “Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ; ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà; wọ́n fa ọrun; wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́, kí ni olódodo lè ṣe?” OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run; OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan, ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò. OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò, ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá. Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú; ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn. Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo; àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀.
O. Daf 11:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú OLúWA. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé: “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ. Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀; wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìji sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?” OLúWA ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; OLúWA ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò. OLúWA ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá ni ọkàn rẹ̀ kórìíra. Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó; àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn. Nítorí, olódodo ní OLúWA, o fẹ́ràn òdodo; ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.