O. Daf 11:1-3
O. Daf 11:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin? Sa kiyesi i, awọn enia buburu ti fà ọrun wọn le, nwọn ti fi ọfa sùn li oju ọṣán, ki nwọn ki o le ta a li òkunkun si ọlọkàn diduro. Bi ipilẹ ba bajẹ, kili olododo yio ṣe?
Pín
Kà O. Daf 11O. Daf 11:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ni mo sá di; ẹ ṣe lè wí fún mi pé, “Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ; ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà; wọ́n fa ọrun; wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́, kí ni olódodo lè ṣe?”
Pín
Kà O. Daf 11O. Daf 11:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú OLúWA. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé: “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ. Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀; wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìji sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin. Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?”
Pín
Kà O. Daf 11