O. Daf 107:4-9
O. Daf 107:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn nrìn ka kiri li aginju ni ibi ti ọ̀na kò si: nwọn kò ri ilu lati ma gbe. Ebi pa wọn, ongbẹ si gbẹ wọn, o rẹ̀ ọkàn wọn ninu wọn. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn, O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa.
O. Daf 107:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn. Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde, lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn, ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.
O. Daf 107:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn. Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè sí OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú tí wọn lè máa gbé Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn, Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.