O. Daf 107:27-30
O. Daf 107:27-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn. O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn.
O. Daf 107:27-30 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí, gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀, ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.
O. Daf 107:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin. Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn. Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́; Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ