O. Daf 107:23-32
O. Daf 107:23-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla. Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú. Nitori ti o paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rẹ̀ soke. Nwọn gòke lọ si ọrun, nwọn si tún sọkalẹ lọ si ibú; ọkàn wọn di omi nitori ipọnju. Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn. O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba.
O. Daf 107:23-32 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun, wọ́n rí ìṣe OLUWA, àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú. Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà, tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè. Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro, wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú, jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí, gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀, ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan, kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà.
O. Daf 107:23-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá. Wọ́n rí iṣẹ́ OLúWA, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè. Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin. Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn. Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́; Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ, Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.