O. Daf 107:19-22
O. Daf 107:19-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀.
O. Daf 107:19-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá, ó tún kó wọn yọ ninu ìparun. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́, kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀.
O. Daf 107:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà wọ́n kígbe sí OLúWA nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́ kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.