O. Daf 107:10-16
O. Daf 107:10-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin; Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo: Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja. Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji.
O. Daf 107:10-16 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n, nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun, wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo. Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn, wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá.
O. Daf 107:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin, Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo, Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já. Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLúWA! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn. Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.