O. Daf 107:1-43
O. Daf 107:1-43 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki awọn ẹni-irapada Oluwa ki o wi bẹ̃, ẹniti o rà pada kuro ni ọwọ ọta nì. O si kó wọn jọ lati ilẹ wọnnì wá, lati ila-õrun wá, ati lati ìwọ-õrun, lati ariwa, ati lati okun wá. Nwọn nrìn ka kiri li aginju ni ibi ti ọ̀na kò si: nwọn kò ri ilu lati ma gbe. Ebi pa wọn, ongbẹ si gbẹ wọn, o rẹ̀ ọkàn wọn ninu wọn. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn, O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa. Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin; Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo: Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja. Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji. Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn. Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn. O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia. Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀. Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla. Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú. Nitori ti o paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rẹ̀ soke. Nwọn gòke lọ si ọrun, nwọn si tún sọkalẹ lọ si ibú; ọkàn wọn di omi nitori ipọnju. Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin. Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn. O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ. Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn. Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia! Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba. O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ; Ilẹ eleso di aṣálẹ̀, nitori ìwa-buburu awọn ti o wà ninu rẹ̀. O sọ aginju di adagun omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi. Nibẹ li o si mu awọn ti ebi npa joko, ki nwọn ki o le tẹ ilu do, lati ma gbe. Lati fún irugbin si oko, ki nwọn si gbìn àgbala ajara, ti yio ma so eso ọ̀pọlọpọ. O busi i fun wọn pẹlu, bẹ̃ni nwọn si pọ̀ si i gidigidi; kò si jẹ ki ẹran-ọ̀sin wọn ki o fà sẹhin. Ẹ̀wẹ, nwọn bùku, nwọn si fà sẹhin, nipa inira, ipọnju, ati ikãnu. O dà ẹ̀gan lù awọn ọmọ-alade, o si mu wọn rìn kiri ni ijù, nibiti ọ̀na kò si. Sibẹ o gbé talaka leke kuro ninu ipọnju, o si ṣe idile wọnni bi agbo-ẹran. Awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ri i, nwọn o si yọ̀: gbogbo ẹ̀ṣẹ ni yio si pa ẹnu rẹ̀ mọ. Ẹniti o gbọ́n, yio si kiyesi nkan wọnyi; awọn na li oye iṣeun-ifẹ Oluwa yio ma ye.
O. Daf 107:1-43 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀, àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú, tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì, láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn, láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù. Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn. Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde, lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan. Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn, ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó. Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n, nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun, wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo. Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn, wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá. Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn. Oúnjẹ rùn sí wọn, wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá, ó tún kó wọn yọ ninu ìparun. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́, kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun, wọ́n rí ìṣe OLUWA, àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú. Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà, tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè. Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro, wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú, jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí, gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró, ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀, ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn. Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan. Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan, kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà. Ó sọ odò di aṣálẹ̀, ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ, ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀, nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi, ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi. Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀, wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé. Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà, wọ́n sì kórè lọpọlọpọ. Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ, kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù. Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro, ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè, ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ọ̀nà. Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú, ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́. Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi; kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀.
O. Daf 107:1-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà OLúWA kí ó wí báyìí, àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá, Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, láti àríwá àti Òkun wá. Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí, wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí wọn ó máa gbé Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn. Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè sí OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú tí wọn lè máa gbé Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn, Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa. Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin, Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo, Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já. Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLúWA! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn. Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì. Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú. Nígbà náà wọ́n kígbe sí OLúWA nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́ kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá. Wọ́n rí iṣẹ́ OLúWA, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè. Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin. Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí OLúWA nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn. Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́; Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ, Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà. Ó sọ odò di aginjù, àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ. Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀; O sọ aginjù di adágún omi àti ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà, wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà tí yóò máa so èso tí ó dára; Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù. Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú, ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí kí ó wo títóbi ìfẹ́ OLúWA.