O. Daf 104:1-35

O. Daf 104:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ. Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita: Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ: Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀. Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai. Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla. Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ. Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn. Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ. Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn; Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun. O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá; Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le. Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn. Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀. Awọn òke giga li àbo fun awọn ewurẹ igbẹ: ati awọn apata fun awọn ehoro. O da oṣupa fun akokò: õrùn mọ̀ akokò ìwọ rẹ̀. Iwọ ṣe òkunkun, o si di oru: ninu eyiti gbogbo ẹranko igbo nrìn kiri. Awọn ẹgbọrọ kiniun ndún si ohun ọdẹ wọn, nwọn si nwá onjẹ wọn lọwọ Ọlọrun. Õrùn là, nwọn kó ara wọn jọ, nwọn dubulẹ ninu iho wọn. Enia jade lọ si iṣẹ rẹ̀ ati si lãla rẹ̀ titi di aṣalẹ. Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ. Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla. Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀. Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn. Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn. Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn. Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun. Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀. O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin. Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi. Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa. Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 104:1-35 Yoruba Bible (YCE)

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ, ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ, ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi, tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́. Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ, tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ. Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò sì le yẹ̀ laelae. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ, omi sì borí àwọn òkè ńlá. Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá, nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn. Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè lọ sí inú àfonífojì, sí ibi tí o yàn fún wọn. O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá, kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì; omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ. Lẹ́bàá orísun wọnyi ni àwọn ẹyẹ ń gbé, wọ́n sì ń kọrin lórí igi. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá. Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀; ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn, ati epo tí ń mú ojú eniyan dán, ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun. Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn, àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn. Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sí, àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi. Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó, abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro. O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò, oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀. O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́, gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sì ń jẹ kiri. Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ, wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ. Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ; wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn. Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀, á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́. OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ. Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀, ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá, nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá. Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ, ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun. Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò, fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò. Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ, nígbà tí o bá la ọwọ́, wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó. Bí o bá fojú pamọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú, wọn á sì pada di erùpẹ̀. Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde, wọ́n di ẹ̀dá alààyè, o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun. Kí ògo OLUWA máa wà títí lae, kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀. Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì, tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín. N óo kọrin ìyìn sí OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ. Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninu nítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA. Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.

O. Daf 104:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Yin OLúWA, ìwọ ọkàn mi. OLúWA Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ. Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ. Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́. Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ, Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ. O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mì láéláé. Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá. Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ; Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn. Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè. Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn. Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka. Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá: Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà. Àwọn igi OLúWA ni a bu omi rin dáradára, kedari ti Lebanoni tí ó gbìn. Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀. Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó; àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro. Òṣùpá jẹ́ ààmì fún àkókò oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀. Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri. Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn. Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́. Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, OLúWA! Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn: ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú, tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye ohun alààyè tí tóbi àti kékeré. Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́ láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn, wọn yóò kó jọ; nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀, a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere. Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́ ara kò rọ̀ wọ́n nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ, wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀. Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ, ni a dá wọn, ìwọ sì tún ojú ayé ṣe. Jẹ́ kí ògo OLúWA wà pẹ́ títí láé; kí inú OLúWA kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀ Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì, ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín. Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí OLúWA: èmi ó kọrin ìyìn sí OLúWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè. Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn bí mo ti ń yọ̀ nínú OLúWA. Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.