O. Daf 103:6-14
O. Daf 103:6-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara. O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli. Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu. On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai. On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa. Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa. Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa.
O. Daf 103:6-14 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA a máa dáni láre a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo àwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli. Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí, bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.
O. Daf 103:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli; OLúWA ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé; Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa. Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa. Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀; Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.