O. Daf 103:1-4
O. Daf 103:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀: Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ, Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade
O. Daf 103:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.
O. Daf 103:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yin OLúWA, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLúWA, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀ Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn, Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé