Owe 9:7-10
Owe 9:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀. Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ. Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ. Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye.
Owe 9:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù, ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀. Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí, kí ó má baà kórìíra rẹ, bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ. Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i, kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè.
Owe 9:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ; kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀. “Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.