Owe 9:1-9
Owe 9:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌGBỌ́N ti kọ́ ile rẹ̀, o si gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ meje: O ti pa ẹran rẹ̀; o ti ṣe àdalu ọti-waini rẹ̀; o si ti tẹ́ tabili rẹ̀. O ti ran awọn ọmọbinrin rẹ̀ jade, o nke lori ibi giga ilu, pe, Ẹnikẹni ti o ṣe òpe ki o yà si ihin: fun ẹniti oye kù fun, o wipe, Wá, jẹ ninu onjẹ mi, ki o si mu ninu ọti-waini mi ti mo dàlu. Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye. Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀. Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ. Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ.
Owe 9:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ọgbọ́n ti kọ́lé, ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró. Ó ti pa ẹran rẹ̀, ó ti pọn ọtí waini rẹ̀, ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀. Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé: “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!” Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé, “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi, kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò. Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè, kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.” Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù, ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀. Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí, kí ó má baà kórìíra rẹ, bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ. Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i, kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀.
Owe 9:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì, ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà. Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀ ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú. “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!” Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé “Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò. Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ; kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.