Owe 9:1-18
Owe 9:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌGBỌ́N ti kọ́ ile rẹ̀, o si gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ meje: O ti pa ẹran rẹ̀; o ti ṣe àdalu ọti-waini rẹ̀; o si ti tẹ́ tabili rẹ̀. O ti ran awọn ọmọbinrin rẹ̀ jade, o nke lori ibi giga ilu, pe, Ẹnikẹni ti o ṣe òpe ki o yà si ihin: fun ẹniti oye kù fun, o wipe, Wá, jẹ ninu onjẹ mi, ki o si mu ninu ọti-waini mi ti mo dàlu. Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye. Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀. Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ. Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ. Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye. Nitori nipasẹ mi li ọjọ rẹ yio ma lé si i, ati ọdun ìye rẹ yio si ma lé si i. Bi iwọ ba gbọ́n, iwọ o gbọ́n fun ara rẹ: ṣugbọn bi iwọ ba iṣe ẹlẹgàn, iwọ nikan ni yio rù u. Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan. O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu. Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe, Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe, Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn. Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi.
Owe 9:1-18 Yoruba Bible (YCE)
Ọgbọ́n ti kọ́lé, ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró. Ó ti pa ẹran rẹ̀, ó ti pọn ọtí waini rẹ̀, ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀. Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé: “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!” Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé, “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi, kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò. Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè, kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.” Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù, ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀. Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí, kí ó má baà kórìíra rẹ, bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ. Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i, kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè. Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn. Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè. Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ, Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀. Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n, oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀, á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú. A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ, àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé, “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!” Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé, “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn, oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.” Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀, ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀.
Owe 9:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀, ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì, ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà. Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀ ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè, láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú. “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!” Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé “Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi sì mu wáìnì tí mo ti pò. Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ; kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀. “Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye. Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ. Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè: bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.” Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀. Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú, ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún. “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!” Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.