Owe 8:4-36

Owe 8:4-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia. Ẹnyin òpe, ẹ mọ̀ ọgbọ́n: ati ẹnyin aṣiwere ki ẹnyin ki o ṣe alaiya oye. Ẹ gbọ́, nitori ti emi o sọ̀rọ ohun ti o dara, ati ṣiṣi ète mi yio sọ̀rọ ohun titọ. Nitori ti ẹnu mi yio sọ̀rọ otitọ; ìwa-buburu si ni irira fun ète mi. Ninu ododo ni gbogbo ọ̀rọ ẹnu mi; kò si ẹ̀tan kan tabi arekereke ninu wọn. Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri. Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ. Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Emi ọgbọ́n li o mba imoye gbe, emi ìmọ si ri imoye ironu. Ibẹ̀ru Oluwa ni ikorira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀na ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo korira. Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ. Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye. Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi. Ọrọ̀ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ̀ daradara ati ododo. Ere mi ta wura yọ; nitõtọ, jù wura daradara lọ: ati ọrọ̀ mi jù fadaka àṣayan lọ. Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ: Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn. Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ. A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà. Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ. Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi: Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye. Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun. Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu: Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye. Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀; Emi nyọ̀ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didùn-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia. Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi: Gbọ́ ẹkọ́, ki ẹnyin ki o si gbọ́n, má si ṣe jẹ ki o lọ. Ibukún ni fun ẹniti o gbọ́ temi, ti o nṣọ́ ẹnu-ọ̀na mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi. Nitoripe ẹniti o ri mi, o ri ìye, yio si ri ojurere Oluwa. Ṣugbọn ẹniti o ṣẹ̀ mi, o ṣe ọkàn ara rẹ̀ nikà: gbogbo awọn ti o korira mi, nwọn fẹ ikú.

Owe 8:4-36 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè, gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n, ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ. Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde, nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú. Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye, wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀. Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka, ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà, nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e. Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé, mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè. Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi, mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro, mo sì ní òye ati agbára. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba, tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso, gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi, ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ, àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ. Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn, ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀, n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí, láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà, nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn, kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko, kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀, tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú, ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé, nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀, tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀, nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá, kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà, èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀, Inú mi a máa dùn lojoojumọ, èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé, inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi, ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi. Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n, ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi, tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi, tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi. Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára, gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”

Owe 8:4-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn, Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye. Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́, Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi. Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀ Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀. Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e. “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú. Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìkórìíra ibi mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára. Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi. Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́, Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún. “Èmi ni OLúWA kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́; A ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú; kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀, Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé. Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀. Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn. “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́, Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ OLúWA. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”