Owe 8:1-4
Owe 8:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi? O duro li ori ibi-giga wọnni, lẹba ọ̀na, nibi ipa-ọ̀na wọnni. O nke li ẹnu-ọ̀na, ati ni ibode ilu, li atiwọ̀ oju ilẹkun. Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia.
Pín
Kà Owe 8Owe 8:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọgbọ́n ń pe eniyan, òye ń pariwo. Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà, ati ní ojú ọ̀nà tóóró, ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú, ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu, ó ń wí pé: “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè, gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí.
Pín
Kà Owe 8Owe 8:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè? Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ìkóríta, ní ó dúró; Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè: Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn
Pín
Kà Owe 8