Owe 7:6-20
Owe 7:6-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li oju ferese ile mi li emi sa bojuwò lãrin ferese mi. Mo si ri ninu awọn òpe, mo kiyesi ninu awọn ọmọkunrin, ọmọkunrin kan ti oye kù fun, O nkọja lọ ni igboro li eti igun ile rẹ̀; o si lọ si ọ̀na ile rẹ̀, Ni wiriwiri imọlẹ, li aṣãlẹ, li oru dudu ati òkunkun: Si kiyesi i, obinrin kan pade rẹ̀, o wọ aṣọ panṣaga, alarekereke aiya. (O jẹ alariwo ati alagidi; ẹsẹ rẹ̀ kì iduro ni ile rẹ̀. Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.) Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe, Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi. Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ. Emi ti fi aṣọ titẹ ọlọnà tẹ́ akete mi, ọlọnà finfin ati aṣọ ọ̀gbọ daradara ti Egipti. Emi ti fi turari olõrùn didùn ti mirra, aloe, ati kinnamoni si akete mi. Wá, jẹ ki a gbà ẹkún ifẹ wa titi yio fi di owurọ, jẹ ki a fi ifẹ tù ara wa lara. Nitoripe bãle kò si ni ile, o re àjo ọ̀na jijin: O mu àsuwọn owo kan lọwọ rẹ̀, yio si de li oṣupa arànmọju.
Owe 7:6-20 Yoruba Bible (YCE)
Mo yọjú wo ìta, láti ojú fèrèsé ilé mi. Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí, mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn, ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n. Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà, ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí, tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn. Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀, ó wọ aṣọ aṣẹ́wó, ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn. Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin, kì í gbélé rẹ̀. Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà, yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀. Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu, yóo wí pẹlu ainitiju pé, “Mo ti rú ẹbọ alaafia, mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí. Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ, mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ. Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi. Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi. Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́ títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa. Ọkọ mi kò sí nílé, ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn. Ó mú owó pupọ lọ́wọ́, kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”
Owe 7:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú fèrèsé. Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n. Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀ Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára. Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé; bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.) Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé: “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi. Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ! Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti. Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi bí i òjìá, aloe àti kinamoni. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́! Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”