Owe 7:1-4
Owe 7:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌMỌ mi, pa ọ̀rọ mi mọ́, ki o si fi ofin mi ṣe ìṣura pẹlu rẹ. Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; ati aṣẹ mi bi ọmọloju rẹ. Dì wọn mọ ika rẹ, kọ wọn si wala aiya rẹ. Wi fun ọgbọ́n pe, Iwọ li arabinrin mi; ki o si pe oye ni ibatan rẹ obinrin
Pín
Kà Owe 7Owe 7:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ. Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè, pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ, wé wọn mọ́ ìka rẹ, kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,” kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ
Pín
Kà Owe 7Owe 7:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ. Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ. Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,” sì pe òye ní ìbátan rẹ
Pín
Kà Owe 7