Owe 7:1-27 - Compare All Versions

Owe 7:1-27 YBCV (Bibeli Mimọ)

ỌMỌ mi, pa ọ̀rọ mi mọ́, ki o si fi ofin mi ṣe ìṣura pẹlu rẹ. Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; ati aṣẹ mi bi ọmọloju rẹ. Dì wọn mọ ika rẹ, kọ wọn si wala aiya rẹ. Wi fun ọgbọ́n pe, Iwọ li arabinrin mi; ki o si pe oye ni ibatan rẹ obinrin: Ki nwọn ki o le pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin ẹlomiran, lọwọ ajeji ti nfi ọ̀rọ rẹ̀ ṣe ipọnni. Li oju ferese ile mi li emi sa bojuwò lãrin ferese mi. Mo si ri ninu awọn òpe, mo kiyesi ninu awọn ọmọkunrin, ọmọkunrin kan ti oye kù fun, O nkọja lọ ni igboro li eti igun ile rẹ̀; o si lọ si ọ̀na ile rẹ̀, Ni wiriwiri imọlẹ, li aṣãlẹ, li oru dudu ati òkunkun: Si kiyesi i, obinrin kan pade rẹ̀, o wọ aṣọ panṣaga, alarekereke aiya. (O jẹ alariwo ati alagidi; ẹsẹ rẹ̀ kì iduro ni ile rẹ̀. Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.) Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe, Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi. Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ. Emi ti fi aṣọ titẹ ọlọnà tẹ́ akete mi, ọlọnà finfin ati aṣọ ọ̀gbọ daradara ti Egipti. Emi ti fi turari olõrùn didùn ti mirra, aloe, ati kinnamoni si akete mi. Wá, jẹ ki a gbà ẹkún ifẹ wa titi yio fi di owurọ, jẹ ki a fi ifẹ tù ara wa lara. Nitoripe bãle kò si ni ile, o re àjo ọ̀na jijin: O mu àsuwọn owo kan lọwọ rẹ̀, yio si de li oṣupa arànmọju. Ọ̀rọ rẹ̀ daradara li o fi mu u fẹ, ipọnni ète rẹ̀ li o fi ṣẹ́ ẹ li apa. On si tọ̀ ọ lọ lẹsẹkanna bi malu ti nlọ si ibupa, tabi bi aṣiwere ti nlọ si ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́. Titi ọfà fi gún u li ẹ̀dọ̀; bi ẹiyẹ ti nyara bọ sinu okùn, ti kò si mọ̀ pe fun ẹmi on ni. Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀. Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa. Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú.

Owe 7:1-27 YCE (Yoruba Bible)

Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ. Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè, pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ, wé wọn mọ́ ìka rẹ, kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,” kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ, kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́, kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin, ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀. Mo yọjú wo ìta, láti ojú fèrèsé ilé mi. Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí, mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn, ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n. Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà, ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí, tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn. Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀, ó wọ aṣọ aṣẹ́wó, ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn. Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin, kì í gbélé rẹ̀. Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà, yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀. Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu, yóo wí pẹlu ainitiju pé, “Mo ti rú ẹbọ alaafia, mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí. Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ, mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ. Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi. Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi. Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́ títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa. Ọkọ mi kò sí nílé, ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn. Ó mú owó pupọ lọ́wọ́, kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.” Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e, bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa, tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté, títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninu bí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn, láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun. Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀, ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa. Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀, ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.

Owe 7:1-27 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ. Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ. Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ. Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,” sì pe òye ní ìbátan rẹ. Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀. Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú fèrèsé. Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n. Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára. Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé; bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.) Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé, “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi. Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ! Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti. Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi bí i òjìá, aloe àti kinamoni. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́! Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.” Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn. Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso. Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.