Owe 6:30-35 - Compare All Versions
Owe 6:30-35 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a; Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan. Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run. Ọgbẹ ati àbuku ni yio ni; ẹ̀gan rẹ̀ kì yio si parẹ́ kuro. Nitori owú ni ibinu ọkunrin: nitorina kì yio dasi li ọjọ ẹsan. On kì yio nani owo idande, bẹ̃ni inu rẹ̀ kì yio yọ́, bi iwọ tilẹ sọ ẹ̀bun di pipọ.
Owe 6:30-35 YCE (Yoruba Bible)
Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi. Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje, ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án. Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí, ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun. Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà, ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae. Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru, kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san. Kò ní gba owó ìtanràn, ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú.
Owe 6:30-35 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á. Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni. Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé. Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san. Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.