Owe 5:3-6
Owe 5:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ: Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji. Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú. Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀.
Owe 5:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ, ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ, ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú, ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè, ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.
Owe 5:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ. Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ, ó mú bí idà olójú méjì. Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú. Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè; ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.