Owe 4:7-9
Owe 4:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye. Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra. On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ.
Pín
Kà Owe 4Owe 4:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n, ohun yòówù tí o lè tún ní, ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga, yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra. Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí, yóo sì dé ọ ní adé dáradára.”
Pín
Kà Owe 4