Owe 4:1-27

Owe 4:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

ENYIN ọmọ, ẹ gbọ́ ẹkọ́ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ̀ oye. Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ̀ ofin mi silẹ. Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-ikẹ́ ati olufẹ li oju iya mi. On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè. Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́. Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye. Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra. On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ. Emi ti kọ́ ọ li ọ̀na ọgbọ́n; emi ti mu ọ tọ̀ ipa-ọ̀na titọ. Nigbati iwọ nrìn, ọ̀na rẹ kì yio há fun àye; nigbati iwọ nsare, iwọ kì yio fi ẹsẹ kọ. Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ. Máṣe bọ si ipa-ọ̀na enia buburu, má si ṣe rìn li ọ̀na awọn enia ibi. Yẹ̀ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rẹ̀, yẹ̀ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ. Nitoriti nwọn kì isùn bikoṣepe nwọn hùwa buburu; orun wọn a si dá, bikoṣepe nwọn ba mu enia ṣubu. Nitori ti nwọn njẹ onjẹ ìwa-ika, nwọn si nmu ọti-waini ìwa-agbara. Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan. Ọna awọn enia buburu dabi òkunkun: nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn ndugbolu. Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi. Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ. Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn. Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye. Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète ẹ̀tan jina rére kuro lọdọ rẹ. Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ. Ronu ipa-ọ̀na rẹ, gbogbo ọ̀na rẹ ni yio si fi idi mulẹ. Máṣe yà si apa ọtun tabi si apa òsi, ṣi ẹsẹ rẹ kuro ninu ibi.

Owe 4:1-27 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀, nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere, ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi. Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi, tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi, baba mi kọ́ mi, ó ní, “Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn, pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀. Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́. Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n, ohun yòówù tí o lè tún ní, ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga, yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra. Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí, yóo sì dé ọ ní adé dáradára.” Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn. Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n, mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́. Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà, nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, má jẹ́ kí ó bọ́, pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ. Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi, má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú. Yẹra fún un, má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀, ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ. Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi, oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan. Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn, ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn. Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́, tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere. Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri, wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù. Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ. Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú, fi wọ́n sọ́kàn. Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn, ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn. Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ, nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè. Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán, kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà. Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ, gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là. Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì, yipada kúrò ninu ibi.

Owe 4:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro Nítorí náà má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀ Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi Ó kọ́ mi ó sì wí pé “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè. Gba ọgbọ́n, gba òye, Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀ Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ. Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ. Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.” Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn. Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà. Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ. Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi. Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi, wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà. Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀. Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ; Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́ Nítorí òun ni orísun ìyè, Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á. Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.