Owe 30:29-31 - Compare All Versions

Owe 30:29-31 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn: Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan; Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀.

Owe 30:29-31 YCE (Yoruba Bible)

Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ, àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan: Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko, kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni. Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ, ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀.

Owe 30:29-31 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere, ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn: Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ, àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.