Owe 30:18-33
Owe 30:18-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀. Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia. Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan. Nitori ohun mẹta, aiye a di rũru, ati labẹ mẹrin ni kò le duro. Iranṣẹ, nigbati o jọba; ati aṣiwère, nigbati o yo fun onjẹ; Fun obinrin, ti a korira, nigbati a sọ ọ di iyale; ati fun iranṣẹbinrin, nigbati o di arole iya rẹ̀. Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́. Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run. Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta. Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́; Ọmọle fi ọwọ rẹ̀ dì mu, o si wà li ãfin awọn ọba. Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn: Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan; Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀. Bi iwọ ba ti ṣiwère ni gbigbe ara rẹ soke, tabi bi iwọ ba ti ronú ibi, fi ọwọ rẹ le ẹnu rẹ. Nitõtọ, mimì wàra ni imu orí-àmọ́ wá, ati fifun imu ni imu ẹ̀jẹ jade; bẹ̃ni riru ibinu soke ni imu ìja wá.
Owe 30:18-33 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú, àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi: ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run, ipa ejò lórí àpáta, ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun, ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí: bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú, á ní “N kò ṣe àìdára kankan.” Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì, ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra: ẹrú tí ó jọba, òmùgọ̀ tí ó jẹun yó, obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́, ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé, sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ: àwọn èèrà kò lágbára, ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára, sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta. Àwọn eṣú kò ní ọba, sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá, sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba. Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ, àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan: Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko, kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni. Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ, ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀. Bí o bá ti ń hùwà òmùgọ̀, tí ò ń gbé ara rẹ ga, tabi tí o tí ń gbèrò ibi, fi òpin sí i, kí o sì ronú. Bí a bá po wàrà pọ̀ títí, yóo di òrí àmọ́, bí ó bá pẹ́ tí a ti ń tẹ imú, imú yóo ṣẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ríru ibinu sókè, a máa mú ìjà wá!
Owe 30:18-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi: Ipa ẹyẹ idì ní òfúrufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami Òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúńdíá lọ́wọ́. “Èyí ni ọ̀nà alágbèrè obìnrin ó jẹun ó sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́. “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín. Ìránṣẹ́ tí ó di ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi; Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá, síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá; síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta; àwọn eṣú kò ní ọba, síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú, síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba. “Àwọn ohun mẹ́ta ní ń bẹ tí ń rìn rere, ohun mẹ́rin ni ó dára púpọ̀ ní ìrìn rírìn: Kìnnìún, alágbára láàrín ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ, àti ọba láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga, tàbí tí o bá ti gbèrò ibi, da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ! Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá, tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”