Owe 3:13-18
Owe 3:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia. Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin.
Owe 3:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí, ati ẹni tí ó ní òye. Nítorí èrè rẹ̀ dára ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ. Ọgbọ́n níye lórí ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o lè fi wé e, ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́. Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ, alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn, ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.
Owe 3:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá. Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà. Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á; àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.