Owe 26:6-12
Owe 26:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o rán iṣẹ nipa ọwọ aṣiwère, o ke ẹsẹ ara rẹ̀ kuro, o si jẹ ara rẹ̀ niya. Bi ẹsẹ mejeji ti rọ̀ silẹ lara amukun, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère. Bi ẹniti o fi àpo okuta iyebiye sinu okiti okuta, bẹ̃li ẹniti nfi ọlá fun aṣiwère. Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère. Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo. Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀. Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
Owe 26:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó rán òmùgọ̀ níṣẹ́ gé ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀, ó sì ń mu omi ìjàngbọ̀n. Bí ẹsẹ̀ arọ, tí kò wúlò, ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀. Bí ẹni fi òkúta sinu kànnàkànnà, ni ẹni tí ń yẹ́ òmùgọ̀ sí rí. Bí ẹ̀gún tí ó gún ọ̀mùtí lọ́wọ́, ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀. Ẹni tí ó gba òmùgọ̀ tabi ọ̀mùtí sí iṣẹ́ dàbí tafàtafà tí ń pa eniyan lára kiri. Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀. Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.
Owe 26:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè. Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè. Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá. Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n. Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ. Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.