Owe 26:3-5
Owe 26:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lagbà fun ẹṣin, ijanu fun kẹtẹkẹtẹ, ati ọgọ fun ẹhin aṣiwère. Máṣe da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki iwọ pãpa ki o má ba dabi rẹ̀. Da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki on ki o má ba gbọ́n li oju ara rẹ̀.
Pín
Kà Owe 26Owe 26:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀. Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀. Dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà agọ̀ rẹ̀, kí ó má baà rò pé òun gbọ́n lójú ara òun.
Pín
Kà Owe 26Owe 26:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè. Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.
Pín
Kà Owe 26