Owe 26:13-22
Owe 26:13-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro. Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀. Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀. Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran. Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti. Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú, Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe? Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da. Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
Owe 26:13-22 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà! Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!” Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ, ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu. Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀ ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ. Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀, dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú. Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró, ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà, tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!” Láìsí igi, iná óo kú, bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán. Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná, bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn a máa wọni lára ṣinṣin.
Owe 26:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀lẹ wí pé: “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.” Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ, ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀. Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀, ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n. Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀. Bí i asínwín ti ń ju ọfà àti ọfà tí ń ṣe kú pa ni ni ènìyàn tí ń tan aládùúgbò rẹ̀ jẹ tí ó sì wí pé, “Àwàdà lásán ni mo ń ṣe.” Láìsí igi, iná yóò kú láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí. Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn dàbí àṣàyàn òkèlè wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.