Owe 26:1-12
Owe 26:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
BI òjo-didì ni ìgba ẹrun, ati bi òjo ni ìgba ikore, bẹ̃li ọlá kò yẹ fun aṣiwère. Bi ẹiyẹ fun iṣikiri, ati alapandẹdẹ fun fifò, bẹ̃ni egún kì yio wá lainidi. Lagbà fun ẹṣin, ijanu fun kẹtẹkẹtẹ, ati ọgọ fun ẹhin aṣiwère. Máṣe da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki iwọ pãpa ki o má ba dabi rẹ̀. Da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki on ki o má ba gbọ́n li oju ara rẹ̀. Ẹniti o rán iṣẹ nipa ọwọ aṣiwère, o ke ẹsẹ ara rẹ̀ kuro, o si jẹ ara rẹ̀ niya. Bi ẹsẹ mejeji ti rọ̀ silẹ lara amukun, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère. Bi ẹniti o fi àpo okuta iyebiye sinu okiti okuta, bẹ̃li ẹniti nfi ọlá fun aṣiwère. Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère. Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo. Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀. Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
Owe 26:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Bí yìnyín kò ṣe yẹ ní àkókò ooru, ati òjò ní àkókò ìkórè, bẹ́ẹ̀ ni iyì kò yẹ òmùgọ̀. Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri, ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká, bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan. Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀. Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀. Dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà agọ̀ rẹ̀, kí ó má baà rò pé òun gbọ́n lójú ara òun. Ẹni tí ó rán òmùgọ̀ níṣẹ́ gé ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀, ó sì ń mu omi ìjàngbọ̀n. Bí ẹsẹ̀ arọ, tí kò wúlò, ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀. Bí ẹni fi òkúta sinu kànnàkànnà, ni ẹni tí ń yẹ́ òmùgọ̀ sí rí. Bí ẹ̀gún tí ó gún ọ̀mùtí lọ́wọ́, ni òwe rí lẹ́nu òmùgọ̀. Ẹni tí ó gba òmùgọ̀ tabi ọ̀mùtí sí iṣẹ́ dàbí tafàtafà tí ń pa eniyan lára kiri. Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀. Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.
Owe 26:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí òjò-dídì tàbí òjò ní ìgbà ìkórè ọlá kò yẹ aláìgbọ́n ènìyàn. Bí ológoṣẹ́ tí ń ṣí kiri tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń rábàbà èpè kò le è mọ́ ẹni tí kò ṣiṣẹ́ èpè èpè kì í jani bí a kò bá ṣiṣẹ́ èpè. Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè. Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀. Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè. Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè. Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá. Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n. Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ. Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.