Owe 24:3-6
Owe 24:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọgbọ́n li a fi ikọ ile; oye li a si fi ifi idi rẹ̀ kalẹ. Nipa ìmọ ni iyará fi ikún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati didùn. Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ. Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun.
Owe 24:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé, òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kó oniruuru nǹkan ìní dáradára olówó iyebíye kún àwọn yàrá rẹ̀ Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ, ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ. Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun, ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.
Owe 24:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀; Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.