Owe 24:10-12
Owe 24:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi iwọ ba rẹwẹsi li ọjọ ipọnju, agbara rẹ ko to nkan. Bi iwọ ba fà sẹhin ati gbà awọn ti a wọ́ lọ sinu ikú, ati awọn ti a yàn fun pipa. Ti iwọ si wipe, wò o, awa kò mọ̀ ọ; kò ha jẹ pe ẹniti ndiwọ̀n ọkàn nkiyesi i? ati ẹniti npa ọkàn rẹ mọ́, on li o mọ̀, yio si san a fun enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.
Owe 24:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú, a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó. Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀, fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada. Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀, ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i? Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀, àbí kò ní san án fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?
Owe 24:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó! Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà. Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?