Owe 23:1-9
Owe 23:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI iwọ ba joko lati ba ijoye jẹun, kiyesi ẹniti o wà niwaju rẹ gidigidi. Ki o si fi ọbẹ le ara rẹ li ọfun, bi iwọ ba iṣe okundùn enia. Máṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀: nitoripe onjẹ ẹ̀tan ni. Máṣe lãla ati lọrọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ. Iwọ o ha fi oju rẹ wò o? kì yio si si mọ, nitoriti ọrọ̀ hu iyẹ-apá fun ara rẹ̀ bi ìdi ti nfò li oju ọrun. Máṣe jẹ onjẹ oloju buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀. Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ li o ri: mã jẹ, ki o si ma mu li o nwi fun ọ; ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò pẹlu rẹ. Okele ti iwọ jẹ ni iwọ o pọ̀ jade, iwọ a si sọ ọ̀rọ didùn rẹ nù. Máṣe sọ̀rọ li eti aṣiwère: nitoriti yio gàn ọgbọ́n ọ̀rọ rẹ.
Owe 23:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára. Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra, kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun. Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú, nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn. Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ, fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ, ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò, bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ. Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun, má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀; nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni. Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!” ṣugbọn kò dé inú rẹ̀. O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ, gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù. Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀, nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.
Owe 23:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn. Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀: nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni. Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run. Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀. Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí: “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ; ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ. Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde, ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè; nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.