Owe 16:6-9
Owe 16:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi. Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia. Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́. Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀.
Owe 16:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò. Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn, a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia. Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ. Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
Owe 16:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù OLúWA ènìyàn sá fún ibi. Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ OLúWA lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà. Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ. Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n OLúWA ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.