Owe 15:1-7
Owe 15:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
IDAHÙN pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọ̀rọ lile ni irú ibinu soke. Ahọn ọlọgbọ́n nlò ìmọ rere: ṣugbọn ẹnu aṣiwère a ma gufẹ wère. Oju Oluwa mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere. Ahọn imularada ni igi ìye: ṣugbọn ayidayida ninu rẹ̀ ni ibajẹ ọkàn. Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye. Ni ile olododo li ọ̀pọlọpọ iṣura: ṣugbọn ninu òwò enia buburu ni iyọnu. Ete ọlọgbọ́n tan ìmọ kalẹ: ṣugbọn aiya aṣiwère kì iṣe bẹ̃.
Owe 15:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè. Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀. Ojú OLUWA wà níbi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere. Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́. Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀, ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni. Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra, ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú. Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀, ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
Owe 15:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè. Ahọ́n ọlọ́gbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde. Ojú OLúWA wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere. Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.



