Owe 14:13-29

Owe 14:13-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ninu ẹrín pẹlu, aiya a ma kãnu; ati li opin, ayọ̀ a di ibinujẹ. Apadasẹhin li aiya ni itẹlọrun lati inu ọ̀na ara rẹ̀: ṣugbọn enia rere lati inu ohun ti iṣe tirẹ̀. Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere. Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju. Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira. Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade. Awọn ẹni-buburu tẹriba niwaju awọn ẹnirere; ati awọn enia buburu li ẹnu-ọ̀na awọn olododo. A tilẹ korira talaka lati ọdọ aladugbo rẹ̀ wá: ṣugbọn ọlọrọ̀ ni ọrẹ́ pupọ. Ẹniti o kẹgàn ẹnikeji rẹ̀, o ṣẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba ṣãnu fun awọn talaka, ibukún ni fun u. Awọn ti ngbìmọ buburu kò ha ṣina bi? ṣugbọn ãnu ati otitọ ni fun awọn ti ngbìmọ ire. Ninu gbogbo lãla li ère pupọ wà: ṣugbọn ọ̀rọ-ẹnu, lasan ni. Adé awọn ọlọgbọ́n li ọrọ̀ wọn: ṣugbọn iwère awọn aṣiwère ni wère. Olõtọ ẹlẹri gbà ọkàn silẹ: ṣugbọn ẹlẹri ẹ̀tan sọ̀rọ eke. Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa li orisun ìye, lati kuro ninu ikẹkùn ikú. Ninu ọ̀pọlọpọ enia li ọlá ọba: ṣugbọn ninu enia diẹ ni iparun ijoye. Ẹniti o ba lọra ati binu, o ni ìmọ pupọ; ṣugbọn ẹniti o ba yara binu o gbe wère leke.

Owe 14:13-29 Yoruba Bible (YCE)

Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn, ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀. Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀. Òpè eniyan a máa gba ohun gbogbo gbọ́, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa kíyèsí ibi tí ó ń lọ. Ọlọ́gbọ́n a máa ṣọ́ra, a sì máa sá fún ibi, ṣugbọn òmùgọ̀ kì í rọra ṣe, kì í sì í bìkítà. Onínúfùfù a máa hùwà òmùgọ̀, ṣugbọn onílàákàyè a máa ní sùúrù. Àwọn òpè a máa jogún àìgbọ́n, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa dé adé ìmọ̀. Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere, àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo. Àwọn aládùúgbò talaka pàápàá kórìíra rẹ̀, ṣugbọn ọlọ́rọ̀ a máa ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí ó bá ṣàánú talaka. Àwọn tí wọn ń pète ibi ti ṣìnà, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbèrò ire yóo rí ojurere ati òtítọ́. Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní. Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n, ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀. Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là, ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́. Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà, níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni. Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè, òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba, olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun. Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ, ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

Owe 14:13-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́. A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀. Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra. Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè, a sì kórìíra eléte ènìyàn. Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀. Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo. Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀ ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní. Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí? Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́. Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni. Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá. Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn. Nínú ìbẹ̀rù OLúWA ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára, yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ìbẹ̀rù OLúWA jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú. Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba, ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun. Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.