Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Owe 13:8-11

Owe 13:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi. Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa. Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà. Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i.

Pín
Kà Owe 13

Owe 13:8-11 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada, ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn, ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.

Pín
Kà Owe 13

Owe 13:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà. Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

Pín
Kà Owe 13
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò