Owe 11:1-8
Owe 11:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
OṢUWỌN eke irira ni loju Oluwa; ṣugbọn òṣuwọn otitọ ni didùn inu rẹ̀. Bi igberaga ba de, nigbana ni itiju de, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu onirẹlẹ. Otitọ aduro-ṣinṣin ni yio ma tọ́ wọn; ṣugbọn arekereke awọn olurekọja ni yio pa wọn run. Ọrọ̀ kì ini anfani li ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo ni igbani lọwọ ikú. Ododo ẹni-pipé yio ma tọ́ ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu ninu ìwa-buburu rẹ̀. Ododo awọn aduro-ṣinṣin yio gbà wọn là: ṣugbọn awọn olurekọja li a o mu ninu iṣekuṣe wọn: Nigbati enia buburu ba kú, ireti rẹ̀ a dasan, ireti awọn alaiṣedede enia a si dasan. A yọ olododo kuro ninu iyọnu, enia buburu a si bọ si ipò rẹ̀.
Owe 11:1-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké, òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí. Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀. Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn, ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n. Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu, ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀. Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n, ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú, ìrètí wọn yóo di asán, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo. OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu, ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.
Owe 11:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA kórìíra òṣùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.