Owe 10:15-29

Owe 10:15-29 Yoruba Bible (YCE)

Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀, ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run. Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè, ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà. Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan, ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni. Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́, ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka, ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n. Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un. Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀, ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye. Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a, ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà. Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ, ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín, ati bí èéfín ti rí sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn, ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú. Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀, ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo. OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́, ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi.

Owe 10:15-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní. Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn, ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà. Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n. Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà, ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí. Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye. Ìbùkún OLúWA ń mú ọrọ̀ wá, kì í sì í fi ìdààmú sí i. Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́. Ìbẹ̀rù OLúWA ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú. Ìrètí olódodo ni ayọ̀, ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo. Ọ̀nà OLúWA jẹ́ ààbò fún olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.